Ibiyinka A. Fuwape
Ibiyinka A. Fuwape (tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1962) jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti ọ̀jọ̀gbọ́n Físísì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ẹni èkejì láti di adarí Yunifásitì Michael and Cecilia Ibru, Yunifásitì aládàáni kan ní Nàìjíríà. Ìpìlẹ̀A bí Ibiyinka Fuwape ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ kẹjọ oṣù Kejìlá ọdún 1962 sínú ìdílé David Ademokun.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Reagan Memorial Baptist Girls Primary School, Yaba, Ìpínlẹ̀ Èkó, ibẹ̀ ni ó ti parí ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.[2] Ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Methodist Girls High School níbi tí ó ti gba ìwé ẹrí O Level kí ó tó tẹ̀síwájú ní Queen's College Yaba láàrin ọdún 1979 to 1981.[2] Ní ọdún 1984, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Bachelor of Science (B.Sc.) nínú ìmọ̀ Físísì Yunifásítì ìlú Ìbàdàn[3] ó sì ṣin ilẹ̀ bàbá rẹ̀ láàrin ọdún 1984 sí 1985.[2] Ní Yunifásitì kan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Master of Science (M.Sc.) ní[2] ọdún 1986 àti àmì ẹyẹ Dókítà(PhD) nínú ìmọ̀ Físísì ní ọdún 1989.[2] Àwọn Ìtọ́kasí
|