Ààrùn ẹ̀dọ̀ A
Aarun ẹdọ A (tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí àkóràn ààrùn ẹ̀dọ̀) jẹ́ líle ààrùn àkóràn ti ẹ̀dọ̀ tí kòkòrò àkóràn ààrùn ẹ̀dọ̀ A fà (HAV).[1] Ọ̀pọ̀ iṣẹlẹ̀ ni kòní àwọn ààmì pàápàá ní ara ọmọdé.[2] Àkókò láàrín àkóràn àti àwọn ààmì, lára àwọn tí o ní, jẹ́ láàrín ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́fà.[3] Bí àwọn ààmì báwà wọn maa ń wà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ wọ́n sì lè pẹ̀lú: ìṣu, èébì, ṣíṣunú, ẹran ara pípọ́n, ibà, àti inú dídùn.[2] Láàrin 10-15% àwọn ènìyàn ní ìrirí wíwáyé àwọn ààmì lákókò oṣù mẹ́fà lẹ́hìn àkóràn àkọkọ́.[2] Ààrùn ẹ̀dọ̀ líle kò sábà ń wáyé ní èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn àgbàlagbà.[2] Ó sábà maa ń ràn nípa jíjẹ tàbí mímu oúnjẹ tàbí omi ẹlẹ́gbin tí ó ní ìgbẹ́ àkóràn.[2] Ẹja eléèpo tí a kò sè dáadaa jẹ́ orísun tí ó wọ́pọ̀.[4] Ó tún lè ràn nípa ìfarakàn ẹni tí ó ní àkóràn.[2] Bí àwọn ọmọdé ò ti ní àwọn ààmì àkóràn bẹ́ẹ̀ wọ́n ṣì le Koran ẹlòmíràn.[2] Lẹ́hìn àkóràn àkọkọ́ ènìyàn kòle ní àkóràn mọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.[5] Ìmọ̀ àisàn nílò àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ bíi àwọn ààmì rẹ̀ ṣe farajọ àwọn ti ààrùn míìrán.[2] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn máàrún tí a mọ̀ ààrùn ẹ̀dọ̀ àwọn àkóràn: A, B, C, D, àti E. òògùn ààrùn ẹ̀dọ̀ A dára fún ìdẹ́kun.[2][6] Àwọn orílẹ̀ èdè kan fọwọ́si níwọ̀nba fún àwọn ọmọdé àti fún àwọn tí ó wà léwu gidi tí akòití fún ní oogùn rẹ.[2][7] Ó hàn pé ó dára fún ẹ̀mí.[2] Àwọn ìwọ̀n ìdẹ́kun míìrán ni ọwọ́ fífọ̀ àti síse oúnjẹ dáradára.[2] Kòsí ìtọjú kan pàtó, pẹ̀lú ìsinmi àti àwọn oogùn fún ìṣu tàbí ṣíṣunú ni a fọwọsí bí o ti yẹ lóòrekoorè.[2] Àwọn àkóràn sábà maa ńlọ pátápátá láìsi àrùn ẹ̀dọ̀ rárá.[2] Ìtọjú fún àrùn ẹ̀dọ̀ líle, bí ó bá wáyé, ni pẹ̀lú Ìrọ́pò ẹ̀dọ̀.[2] Lágbayé láàrín 1.5 mílíónù àwọn ìṣẹlẹ̀ ààmì maa ń wáyé lọdọọdún[2] èyí tí o ṣèéṣe àwọn àkóràn mílíónù ọ̀nà mẹ́wà ní gbogbo.[8] Ó wọ́pọ̀ l’áwọn apa ẹkùn kan lágbayé tí wọn kìí tíṣe ìmọtótó dáradára àti tí kòsí omi tó.[7] Ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ṣẹ̀ẹ̀ṣẹ̀ ń gbèrú ìdá 90% àwọn ọmọdé ni o tiní àkóràn ní ọmọ ọdún 10 wọn kòsì le ni mọ́ ní àgbà.[7] O máa ń ṣẹlẹ̀ níwọ̀nba ní àwọn orílẹ̀ èdè tí o ti gbèrú níbi tí àwọn ọmọdé kòní àkóràn ní kékeré tí kòsí sí ìwọ́pọ̀ ìfún lóògùn.[7] Ní 2010, àrùn ẹ̀dọ̀ líle A fa ikú 102,000.[9] Àyajọ́ ọdún ààrùn ẹ̀dọ̀ àgbayé ó maa ń wáyé lọ́dọọdún ní July 28 láti mú kí àwọn ènìyàn mọ́ọ̀ ààrùn ẹ̀dọ̀ líle.[7] Àwọn ìtọ́kasi
|