Ọ̀nà tí a lè pín òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá síỌ̀NÀ TÍ A LÈ PÍN ÀWỌN ÒRÌṢÀ ILẸ̀ YORÙBÁ SÍ Ẹnu kò kò lórí iye àwọn òrìṣà tó wà nílẹ̀ Yorùbá. Bí àwọn kan se sọ pé ọ̀kànlénígba òrìṣà ló wà ní aàfin Ọ̀ọ̀ni bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn kan ń sọ pé irinwó òrìṣà ó lẹ́ ọ̀kan (401 deities) ló wà lóde ìṣálayé à ò lè sọ pàtó iye òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá tó wà pẹ̀lú iye òrìṣà tí a ti mẹ́nu bà lókè yìí, nítorí pé kì í ṣe gbogbo òrìṣà tó rọ̀ láti òde-ọ̀run wá sí òde-ìṣálayé ni à ń pè ní òrìṣà. A rí àwọn abàmì nǹkan mìíràn tí àwọn ènìyàn sọ di òrìṣà. Bẹ́ẹ̀ a sì rí àwọn alágbára àtijọ́ tí a sọ di ẹni òrìṣà èyí tí Òrìṣà Bàbá Ṣìgìdì tí ìwádìí yìí dá lé lórí wà. Pẹ̀lú gbogbo àlàyé wọ̀nyìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ onímọ̀ ló ti gbìyànjú láti pín Òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá sí oríṣìírìíṣìí ọ̀nà. Àwọn kan pín in sí ọ̀nà méjì, àwọn kan pín in sí ọ̀nà mẹ́rin. Bákan náà ni a tún rí àwọn kan tí wọ́n pín òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá sí ọ̀nà márùn-ún. Awolàlú àti Dọ̀pèmú (1979:73) gbà pé ọ̀nà mẹ́ta ni a lè pín òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá sí.[1] Ìpínsísọ̀rí àwọn òrìṣà
Lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn kan ti ṣe lóríi ọ̀nà tí a lè gbà pín àwọn òrìṣà ìlẹ̀ Yorùbá, nínú èrò tèmi, pínpín òrìṣà sí ìsọ̀rí mẹ́rin ni mo fara mọ́ nítorí ìsọ̀rí yìí ló ṣàlàyé fínnífínní gbogbo nǹkan tí a kà sí òrìṣà nílẹ̀ Yorùbá. Àwọn ọ̀nà mẹ́rìn tí àwọn onímọ̀ pín in sí ni: òrìṣà atẹ̀wọ̀nrọ̀, àwọn ẹ̀dá tí a sọ di òrìṣà lẹ́yìn ikú wọn, àwọn òrìṣà nípa ìbí, àti àwọn àdàmọ̀dì òrìṣà. Àwọn Ìwé ti a ṣamúlò
Láti ọwọ́: Adéoyè, Adérónkẹ́ Motúnráyọ̀ (Oṣù ọ̀pẹ, 2007)
Àwọn itọ́kasí
|